Ẹ Pàdé Ọ̀dọ́mọdébìnrin Ayanwura Tó Ń Fi Ìlù Lílù Yin Olódùmarè



A bá Ọ̀dọ́mọdébìnrin Sofiyat Ọláídé tí àwọn èèyàn mọ̀ sí Àyánwúrà àti ìyá rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa bí ọmọ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní lu ìlù lọ́nà àrà láti kékeré rẹ̀.

Ìyá Sofiyat sọ púpọ̀ lọ́rọ̀ nípa bí àwọn ènìyàn kò ṣe nífẹ̀ẹ́ sí ìṣe ọmọ náà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo wọn ni wọ́n ń kan sáárá sí iṣẹ́ rẹ̀ lásìkò yìí tí wọ́n sì ń fọ́n àwọn fọ́nrán orí ayélujára rẹ̀ ká.

Ó rọ àwọn òbí nígbẹ̀yìn láti gbárùkù ti ẹ̀bùn àmútọ̀runwá àwọn ọmọ kí wọ́n sì kún fún àkíyèsí, nítorí Olúwa Ọba ló mọ iṣẹ́ àṣelà.

All rights reserved. This material, and other digital content on this website, may not be reproduced, published, broadcast, rewritten or redistributed in whole or in part without prior express written permission from PUNCH.

Contact: [email protected]



Source link

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *